Ka àwọn ayokà isàlè yil, ki o si dáhún àwọn ibéèrè tí ó tèlé won.
Òpọ̀ ọdún sẹ́yìn, àșà Yorùbá jẹ́ àfihàn ìdánimọ̀, ìbùkún àti ìpẹ̀yà fún àwọn tí wọ́n bá tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. Àșà àti ìṣe Yorùbá dá lórí ìbáșepọ̀ rere, ìbùkún
àwọn àgbà, ìtẹ́lọ́run ìdílé, àti ìmọ̀ràn tí ó dá lórí ọgbọ́n àwọn baba-nlá wa. Ní gbogbo agbondan Yorùbá, ìyàwó tí a fẹ́ sílẹ, orúkọ tí a fún ọmọ, àwọn
àșà bí a șe ń sajọyọ̀, tàbí bó ṣe yẹ kí a ṣe ìrántí ẹni tó kú, gbogbo wọ́n ní ìtumọ̀ púpọ̀.
Șùgbón, ní àgbáyé òde-òní, pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti imọ̀-ẹrọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọde àti àwọn ọdọ ti kọ̀ ẹ̀kọ́ àti àșà àwọn baba wọn sílẹ̀. Wọ́n ń fi ẹ̀sùn
kàn an pé àșà jẹ́ ohun ateyinwa, kó sì ní ọ̀rọ̀ tó wúlò mọ́. Kíákíá ni wọ́n fi ń gbàgbọ́ pé àwọn àșà tó jẹ́ ti àwọn oríl-èdè yòókù dàgbà ju tiwọn lọ.
Ọpọ̀ àwọn obi àti olùkọ́ ló ti wá fidí re mulẹ̀ bayi pé àìmọ̀ àșà lórí àwọn ọmọde ń fa ìjìyà àti ìtànkálẹ̀ ìbànújẹ nínú awujọ. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ tí kò mọ̀
ìtẹ́ríba, kò ní lè mọyì àgbà, kó sì ní ifọkàn tán láti fi ọgbọ́n gbà ìpinnu. Nípa bẹ́ẹ̀, àṣà Yorùbá kò yẹ kí ó kú tàbí di aimo, ó yẹ kí a fi ran àwọn ọmọ wa
lọ́wọ́ nínú ẹ̀kọ́, isé, àti ìgbésí-ayé won.
Kí ni àșà șe fún ìdílé ní ibẹrẹ àpilẹ̀kọ?
Àșà Yorùbá jẹ́ àfihàn ìtẹ́lọ́run ìdílé àti ìbùkún.
Contributions ({{ comment_count }})
Please wait...
Modal title
Report
Block User
{{ feedback_modal_data.title }}